Home iroyin Agbébọnrìn, Stephen Paddock sekú pa àádọ́rin ènìyàn l’Amerika
iroyin - October 3, 2017

Agbébọnrìn, Stephen Paddock sekú pa àádọ́rin ènìyàn l’Amerika

Ana ojo isinmi ni ayeye odun orin ati ijo “Music Festival” ni ilu Las Vegas ni Amerika ti n lo lowo ki “odaran, eye tii mu osan” to bere si ni yin ibon si aarin ero. Olorun nikan lo mo ogbon to da si ibon ati igba to ti n gbaradi fun ise ibi naa. Laarin iseju aaya, eni ibi naa ti pa eniyan mokandinlogota (59), sugbon nigba ti ile fi maa mo, iroyin ti gbee pe eniyan to ba isele naa lo ti n wo aadorin (70) nigba ti eniyan bii eedegbeta (500) fara pa yanna-yanna.

Orisiirisii iwadii lo ti n lo lowo nipa Stephen Paddock naa, awon agbofinro ti mo ibi to ti ra awon ibon re, won ti mo ololufe re ti ko si nile bayii, orile-ede Tokyo lo wa bayii. Awon agbofinro ni titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo, ko dabii wi pe enikankan baa lowo si ise ipaniyan naa.

Iroyin tun gbee pe lati igba ti oju ti la ni orileede Amerika, won ko ranti igba ti enikan pa eleran ara bii tire to po bee ri. Iroyin ile Amerika kan gbe iye awon eniyan ti emi won n sonu ninu isele kan tabi omiran jade lati odun 1982 titi di odun yii. Pulse nightclub ni Orlando mu emi eniyan mokandinlaadota (49) lo, Inland Regional Centre, San Bernardino mu emi eniyan merinla (14) lo. Navy yard Washinghton DC mu emi mejila (12), Sandy Hook Elementary School, Newtown padanu eniyan metadinlogbon (27),Movie theatre, Aurora padanu eniyan mejila ati bee bee lo. Giraafu naa ree nisale yii …

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…