Home ÀRÒJINLẸ̀ Ọ̀kánjúà Baba ọ̀lẹ
ÀRÒJINLẸ̀ - October 2, 2017

Ọ̀kánjúà Baba ọ̀lẹ

Mo ki yin, e ku ikale n beun. Iwa okanjua, ojukokoro ati ainitelorun ti so elomiran, papaajulo awon olori wa, di eni yepere lawujo. Ohun ti opolopo elomiran fe je ko je ki won gbon. Ojo melo  la fe lo laye gan-an ti a wa n wo ewu irin?. Eru bami, aya mi si ja, nigbati mo gbo iye owo rogurogu ati opolopo ile awosifila olowo iyebiye ti minisitita alakoso tele ri fun oro epo robi (NNPC), arabinrin Alinson Madueke nikan ko si apo ara re. Iya  na ko tile bikita fun igbesi aye awon omo Nigeria, papaajulo awon ogo weere ati awon  odo ti kori ise se. Ko tile ro ti awon ti kori ounje je ati awon ti ko ri ile gbe, pelu awon omo alailebi ati awon ti ko lara, ni eyi to je pe ko si ireti fun ojo ola won. Gbogbo ohun ti o je iya yi logun ni iwa imotara eni nikan ati kiko owo ara ilu je. Amori i ba ku ni iwa aibikita ti odaju abiyamo iya na gunle. Bamubamu ni moyo, n ko mo pe ebi n pa omo enikookan ni igbesi aye ti iya aafin Alinson Madueke gunle. Eleyi je ohun to seni laanu pupo. Omugo eniyan ko mo pe “iyan ogun odun a ma jo ni lowo, oro ti a ba fi eru kojo ki i tojo” ni owe Yoruba so.

Gbogbo wa n pariwo pe ilu yi ko ni idagbasoke. Ba wo ni ilu se fe ni idagbasoke nibi ti enikan soso ti ni ile tabi ra ile bi mejidinlogota (58 houses), ati  egbelegbe owo bi  billion ati trillion naira, ki a ma i ti wa so ti  owo okeere bi dollars, pound sterling ati beebelo. O ye ka beru Olorun!. Ki la n je ti ki i tan, a fi ola Olorun nikan. Odaju eeyan lo n huwa bi ti iya aafin Allinson Madueke. Eni  a ba pe ni iyawo ile ati alabiyamo tooto ko ye ko  ye ko hu iru iwa odaju bayi. Eni a ni ko kin ‘ni leyin to fegun sowo ni oro iya na. Ohun itiju gbaa lo je fun orileede yi ati awon obinrin ilu yi pelu.

O da bi eni pe ijoba funra e tubo n fun awon obayeje ilu yi lagbara lati tubo ma gberu si ninu iwa ibaje.  Igbese ijoba lori igbogun ti iwa ibaje nilu yi ko i to. Lati fi opin si iwa ibaje patapata, ijoba gbodo gbena woju awon ti ajere iwa ibaje ba simo lori, lati ri pe won fi iru awon odaran be si inu tubu (jail) fun igba pipe lati ko awon yoku logbon. O seni laaanu pe lati igba ti ijoba ti n mu awon odaran wonyi, ko i ti ju enikankan sewon ninu won. Eyi lo fa ti ko je ki won fi be jawo ninu iwa ibaje, eru ko si ba won lati tubo mo ko owo ara ilu je pelu. Ki ijoba tun ero re pa lori igbogun ti iwa ibaje ti won gunle.” A i to  eyin ka la n fowo bo, oju afoofotan, ija ni da sile. Ba a ba je osakala a je osakala, osakala sokolo ko ye omo eniyan. O tun di lose to n bo.

E feyi kogbon.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…