Home iroyin Mo bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ Kogi – Melaye
iroyin - September 26, 2017

Mo bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ Kogi – Melaye

Senato Dino Melaye to n soju iwo oorun ipinle Kogi lo pe ipade awon oniroyin ni ana ojo Monde, ojo karundinlogbon, osu kesan-an, odun yii pe oun ti bo lowo awon olote ti won fe yeye oun dandan. O ni emi oun ni won koko n lepa ki Olorun to ko oun yo lowo won. O ni leyin eyi ni iwe eninni jade pe oun ko soju iwo oorun Kogi daadaa, ki oun si maa pada bo wa sile.

Melaye ni oun ko ri oran ti oun da ninu bi oun se n pe gomina Yahaya Bello si akiyesi awon nnkan kookan ni igba kan.O ni nnkankan ti oun funra si pe o fa ogun ati ote fun oun niyen.

Senato yii ni iwe eninni ti won ko lati pe oun pada ko lagbara ju aadorun-un ojo lo ni eyi to ti pe ni ose to koja gege bi iwe ofin Naijiria ti odun 1999, abala kokandinlaadorin. O ni koda awon ore timo-timo oun ti n ki oun ku ajabo lowo ogun ati ote naa.

Melaye ni oun pe awon oniroyin lati le je ki won mo ibi ti nnkan de duro nitori gbogbo eti to ba gbo alo naa ni o ye ki o gbo abo. O ni bayii oun naa ti salaye fun agbejoro oun iyen, Oloye Mike Ozekhome (SAN) lati ba oun pe ajo eleto idibo ipinle Kogi INEC lejo, lori bi won se ko arumoje iwe ti won ni awon to dibo fun oun towo bo lati fi pe oun pada.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…