Home Orisirisi Wahala bẹ́ sílẹ̀ n’Ìbàdàn! Àwọn jàǹdùkú da ìbọn bo ààfin Olúbàdàn
Orisirisi - September 25, 2017

Wahala bẹ́ sílẹ̀ n’Ìbàdàn! Àwọn jàǹdùkú da ìbọn bo ààfin Olúbàdàn

 

 

Olorun lo yo Olubadan ti Ibadan, Oba Saliu Adetunji, ati Oloye Barrister Sharafadeen Ali, pelu awon oniroyin meta kan ni owuro oni.

Ti ko ba je agbara Olorun ni, boya nnkan miiran ni a ba maa wi, tori awon janduku kan da ibon bo aafin Kabiyesi ni Popo Yemoja, lasiko ti o n fi awon baale miiran je ni Ibadan.

A gbo pe moto Siena kan ni awon janduku naa gbe lo si aafin, ti won n pariwo pe, ‘Ko ni daa fun iyalaya yin! E jade bi e ba to bee!”

A gbo pe bi won se n pariwo ni won n yinbon peerepe.

Awon oniroyin ti oro naa kan ni Ogbeni Femi Atoyebi to n sise pelu THE PUNCH, Ogbeni Demola Babalola ati Jeremiah Oke.

Lati nnkan bii osu kan seyin ni agbada ko ti gbona, ti agbado o ta mo ni Ibadan, nigba ti Gomina Abiola Ajimobi gbe awon oba mokanlelogun miiran dide.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…