Home iroyin Agbébọnrìn ya lu ààfin Olúbàdàn
iroyin - September 25, 2017

Agbébọnrìn ya lu ààfin Olúbàdàn

Ilu Ibadan ko fararo ni aaro oni ni nnkan bii aago mokanla aabo si mejila ni igba ti awon agbebonrin ya lu aafin Olubadan ti ile Ibadan, Oba Saliu Adetunji. Won duro si enu ona aafin naa pelu moto Sienna alawo dudu, won si n rojo ibon lako-lako si aafin naa.

Ikunle abiyamo lo ko awon oniroyin bii pepa merin yo nitori pe bi moto won se n de enu ona aafin naa ni awon agbebonrin naa de, oro wa di boo-lo, koo yago lona. “Oro ko ba ojugun lo ni ohun ko leran lara” inu gota idoti idaminu ni awon oniroyin rakoro gba sa asala fun emi won.

Elegbe gbogbo moto ti awon agbebonrin ba ni ita ni won bere si ni da ibon bo. Fun bii iseju mewaa ti won fi n yinbon, ko si eso kankan bii olopaa tabi soja kankan to daa pada titi ti won fi lo. Ona adugbo Molete si Popoyemoja ni moto won gba lo.

Gbogbo awon to n yinbon naa ko koja merin sugbon didun ibon naa dabi wi pe ogorun-un eniyan lo n yin in.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…