Orisirisi - September 25, 2017

Paga! PSquare fo yangayanga: Peter ke gbajare pe Paul fe pa oun!

Opin ti wa de si ajosepo awon gbajugbaja ibeji to da egbe osere PSquare sile o.

Leyin opo odun ti won ti gbayi nile ati l’oko, okan lara won, iyen Peter, ti so pe oun ko se ajosepo ise orin pelu Paul ati egbon won, Jude mo.

O ni won ko feran oun ati ebi oun, leyii to tumo si oun ati iyawo re, Lola.

O tun so pe isubu oun ki ikeji oun n wa, to si ti so pe oun maa pa oun.

Lati fi oun to wa lokan re han, Peter ti ko leta pataki kan si loya won, iyen Festus Keyamo, to so fun un pe o to gee, alubata kii darin.

O ni oun fe ma ba igbesi aye oun lo funra oun, pelu iyawo ati awon omo oun.

Odun to lo ni nnkan ti koko fee daru patapata ninu idile PSquare.

Leta ti Peter ko si Keyamo naa la te jade yii, gege bi Linda Ikeji se koko gbe e jade.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…