Home iroyin Ipo kinni ipinle Ekiti ninu NECO fi itoju oluko wa han- Fayose
iroyin - September 16, 2017

Ipo kinni ipinle Ekiti ninu NECO fi itoju oluko wa han- Fayose

Odoodun ni idanwo NECO (National Examiation Council) maa n waye ni orileede Naijiria. Odun to koja ni ipinle Ekiti koko jawe olubori lati bi odun meloo kan seyin ti ifaseyin ti n ba eto eko ipinle ni awon ile Yoruba paapaa julo ninu WAEC (West African Examination Council). Ipinle Ekiti tun pegede lodun yii nipa jija ewe olubori.

Eyi mu ki inu gomina Fayose dun, o si fun u laaye lati soro si awon ti won benu ate luu lodun to koja ti won koko yege. Awon eniyan ni ise ti gomina Fayemi se sile ni o je. O wa tun n fi to awon ara ilu leti pe ijoba oun si tun maa gbaa ni odun to n bo.

Fayose tun ni ti awon ara ipinle Ekiti ba si fe maa gbaa lo ki won dibo won fun igbakeji oun to maa dije lodun to n bo, iyen Ojogbon Kolopo Olusola. O ni Ojogbon naa lo n foju to eto eko ipinle naa. Gomina fi kun oro re pe ko si bi awon ko se ni maa jawe oubori nitori ko si ipinle to moyi tabi toju oluko bi ipinle Ekiti. O ni bi ilu se le to, awon mo bi awon se n dogbon sii ti awon fi n se ike awon oluko nitori awon omo awon ti won je ojo ola ipinle Ekiti ati Naijiria lapapo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…