Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE Ibowo fun agba
ÀṢÀ ÀTI ÌṢE - September 16, 2017

Ibowo fun agba

Aye n lo a n to o, olaju ,olaju, oju la tan, ohun gbogbo polukurumusu. Ogbon agba ko wulo mo,loju awon ewe,n ti ko tona rara ( igbo mimu, gigerun buruku sori, tatuu repete ni toju timu berekete, irun alusi lori bii talaagana, akisa ohun aso ihoho  saa , bi eni adahunse n fegbaa fun lohunje.) Gbogbo iwa awobanuje wonyi to gun rege loju u tiwon. Laye ojosi, idobaale ohun ikunle lomo idunu fii ki obi laaro boju ba ti n mo, toye si n la. Bee, obi yoo ki oriki omo , pelu iwure atikun wa.Ko si bi omo ti le dagba to lowo obi, omo si ni. Omo ko gbodo koro si obi e lenu,eewo ni.Awon nnkan wonyi la gbonju mo, taye si n gun rege.lya ko si nii satako baba, lori itosona omo won laye-laye, tori iya atata mo n ti ojo iwaju omo je. Idi pataki ti obi fi ma a n fohun sokan lati toju omo laye atijo ni ki omo le e ni aseyori alailegbe, ki irufe omo bee o si le e kekoo bi oun naa yoo se to omo ti Olodumare ba fi taa lore nigba ti oun paapaa ba da duro bii ebi.
Oju meji nii bimo, igba oju nii wo, nigba naa,iya ati baba nikan ko ni olutona omo, ebi , ara, iyekan ati ojulumo nii pa imo po setoju omo .ldile ti omo ti wa se pataki, onikaluku ni o mo itumo ati pataki oruko.ldi niyi ti koowa fi maa n toju oruko re nigba naa, biigba ti ahun n toju nnkan ini re.Bi omo ba dagba, ti o si deni ti o ti to eru awujo o ru, oruko idile irufe omo bee wa ninu nnkan ti awon eeyan maa n wo mo omo lara, ninu awon igbese bii igbeyawo, ifini joye, fifi ni se adari nibikan ati bee bee lo.
Yooba nigbagbo pupo ninu oruko rere, won si gba pe oruko rere ni opakutele iwa omoluabi ti won fi le fi ohun rere lo eeyan lawujo yoruba laye ijohun. Won kii gbe eru awujo ru asa eniyan,  ayaafi ki onitoun je oniwa pele,omoluabi eniyan ti o fi gbogbo ara sogbon.
Omode to n yaju si agba, awon agba kii fi gbogbo enu soro siru omo bee, itan ni won yoo pa fun un, pe aso to kojo to n gun un gara gara, agbalagba ti da ilopo ilopo re sori akitan.Omode to ra aja, to so ajaa re ni tagba mase ni……. Omode to bere to n desa okete…. Omo to  wo sunsun, to fiwa olaju sin baba e ni ihooho, asise nla gbaa ni yoo je funrufe omo bee, ti ko ba je ki aburo o re o ni iriri igbese e re.Aigun aye lode oni, e debi i re ru gbogbo awon tolaju asa atohunrinwa ti so domugo sugbon tawon alaimokan eeyan bii tiwon n gbosuba a kare fun bi i ologbon.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…