Home Èfè ati Àwàdà Ailera Aare Buhari
Èfè ati Àwàdà - September 16, 2017

Ailera Aare Buhari

Mo ki yin pe e ku amojuba ose titun. Arun ti n sogoji ni n se oodunrun (orunla), ohun to n se aboyade, gbogbo oloya lo n se. Be gele ni oro ailera Aare wa, Mohammadu Buhari se ri. A dupe pe baba naa ri itoju gba ni oke okun lohun, o lo layo, o si de ni alaafia, leyin osu meta ni ilu London. Ki baba naa muse se la i fi akoko sofo rara nitori oro ilu yi ko gba ohun ti a n fi owo yoboke mu rara, ki i si se ohun ti olori to ba mo oun to n se le fi jafara rara. Orilede to nira die lati sejoba le lori ni ilu Nigeria wa yi. ‘’Yoruba bo won ni, ‘’eni soju ko da bi eni to seyin’’. Ka dupe lowo Ojogbon Yemi Osinbajo, igbakeji Aare to dele de baba naa ti ko je ki isakoso ilu yi daru. Loju ota eni, bi ka rajo ka mo bo ni. Gbogbo alangba lo danu dele, a ko mo eyi tinu n run.

Nibi ti oro de duro bayii lori ailera Aare Buhari, o ye ki a so otito oro funra wa. Ki Aare ati alabasisepo re tera won ninu, ki won si ba ara won so otito oro lori boya Aare yo le maa te siwaju ninu isakoso ijoba ilu yi tabi ko ni le tesiwaju, nitori okun inu la fi n gbe tita. Ti Aare Buhari ba mo pe ailera oun ko ni le fi aaye gbaa lati te siwaju ninu isakoso ilu yi, a dara pe ki Aare kowe fi ipo re sile, ki o si lo wa itoju to peye fun ailera ara re. Ki o gbe ijoba sile fun igbakeji re, Yemi Osinbajo lati maa se ijoba ilu yi lo. Ki Aare ma fi ailera re sere rara, bakan naa si ni ki o ma fi ailera re di itesiwaju ati irepo ilu yi lowo. Ki o ma se je ki wahala ilu yi gba emi re lai pe ojo.

Awon ebi Aare, iyawo ati awon omo re si nilo re ni iwon igba ti emi re ba si wa. Baaku ise o tan. Ki Aare ma fi agidi-kanpa se ijoba ti agbara ati alaafia re ko ba gbe. Ife ati itesiwaju orilede yi lo ye ko je Aare wa logun, enikan ki i si je awade ni oro aye yi. Bi ori ba baje, dandan ni ki o kan ara yoku. Asiko niyi ti Aare Mohammadu Buhari  gbodo tun ero re pa lati gbe igbese to to fun anfaani orilede yi ati awon eniyan inu re, ti o ba je nitooto ni baba naa nife ilu yi denu. Ki o ma se teti si oro awon elenu mari-maje, awon ti won ko ko ki  osan doru nitori imo-tara-won nikan. Ki baba naa ma se gba lati je ki won lo oun fi fa owo aago ilu yi lo seyin nitori nnkan ti won fe je. Ka tun fi ire pade lose to n bo.

E feyi kogbon.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…