Home iroyin Ààrẹ Buhari fajú ro sí àwọ̀n gómìnà nípa owó osù
iroyin - September 12, 2017

Ààrẹ Buhari fajú ro sí àwọ̀n gómìnà nípa owó osù

Aare Mohammadu Buhari ti orileede yii ni inu oun ko dun bi awon gomina kan se n je owo osu mefa, mejo ati owo ifehinti awon eni eleni.  O ni owo osu yii naa ni opo awon osise yii n ro omi ro iyefun si.

Buhari ni ko si idi pataki to fi ye ki won je awon osise yii lowo oogun won. O ni nitori “majiya ni awon se n ya majiya lofa”. O ni ki ebi ma baa pa awon osise yii ni ijoba apapo se fun won ni owo “paris club”.

Aare n salaye yii ni igba ti awon oba alaye orileede lo kii kaabo ni ilu Abuja. Awon oba yii ba Aare dupe alaafia, won si gbadura emi gigun lati le ko ilu yii je pe fun un.

Awon asoju elekun-jekun oba to soro nibi ipade naa ni Ooni ti ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi fun ekun Soutwest, Lamido Adamawa fun ekun Northeast,  Eberechi Dick  fun ekun Southeast, Jacob Buba Gyang ni fun ekun Northcentral, Jaja ti Opobo lo soju ekun Southsouth nigba ti Emir ti Kano, Alhaji lamido Sanusi lo soju ekun Northwest.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…