Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE Ọ̀làjú àbí ìtìjú
ÀṢÀ ÀTI ÌṢE - August 26, 2017

Ọ̀làjú àbí ìtìjú

Femi Akinsola (Ibadan)

Yooba bo won ni eeyan to so ile nu ,o ti so apo iya ko.Bi eniyan si ta araale re ni ponto, ko le e ri ra ni owon. O ye ki a salaye funra wa pe,yooba je eya kan ti o mo riri iwa omoluabi,ti o si koriira ohunkohun ti o jo mo egbin tabi abuku.Eyi ri be e tori pe iran yooba,nibi gbogbo lagbaalaye ni won gbo agboye n ti a n pe ni “OMOLUABI”  eyi si ma a n duro bi ijanu,fun awon iwa ati isesi i won lopolopo igba ti won ba de awujo kan tabi omiran.
Ojulowo Iran omo  yooba ti ni iwa ti o se e mu yangan lawujo,lati igba iwase.Yooba ko si ninu iran ti i wo esin elesin sa ere.Bi eni kan ba so pe awon eebo lo la Iran yooba loju, onitoun nilo iranwo awon oni “MIKIWO” .E ma ka oro yii si eebu o.O gba arojinle,ki a le e fura gidi gidi siru u won,ko mo je awon teebo yan Iran an won lale.Ko ri be e,o jo be e,gbogbo iwa ti won n pe lolaju asiko yii,ti n hun gbe eeyan leebi. Gbogbo n ti won mo Iran yooba mo,ti won fi n pewa ni omoluabi ni won ti baana e  so di sinimo awo jawo leri,dowo boju loja.
Ni aye  atijo, oro enu eniyan,irisi eniyan,nipa aso wiwo,irun ti o ge,di,tabi ko si ori,pelu aso ati bata ti o wo,yala lokunrin tabi lobinrin,omode tabi agbalagba,ma a n je atoka idile ti onitoun ti wa.Die ninu n ti a menuba yii,lo n sapejuwe iran yooba gidi ni onitoun,ti o n se n ti o to ti o ye.
Won ki i woso to feya ara won sile,okunrin mo ni ilana imura ti e,obinrin ni ti e,ko papo,koda ki won  kowon papo sinu apere kan soso.
Iran yooba je iran ti o loju,ni ibamu pelu asa ati ise won. O yami lenu pe ogooro iwa ati ise awon ti n so ede yooba lenu lawujo yii lasiko ti a wa yii,tako n ti a mo iran ojulowo omo yooba mo.Gbogbo isesi i won lo tako n ti won n peraawon. Okunrin n firun,won n ilu imu ati eti, pelu yeti.Won fai je Dada,won fi gbogbo ori ta koko bi eni Sanpona n binu si.N ti o ta koko irun a kun mo won lori,bi aginju iberu. Bi won si tun tawo gan aso teebo lo ku loke okun,gbogbo re ni yoo ya gberegede,ku fo  fo fo yika ara bi ajere.Bi won ba wa pewon lalaagana,won a binu faraya.ltiju gba a lo je,pe ibi a ti n reti ogbon,idakeji la ri.Aja iwoyi tiwon  n leranko iwoyi,eranko n leranko lai si ninu aginju. “Bomode o ba ponu,bo le logun odun ,o ye ko mo baye se je”Orin oloogbe Haruna lshola,Baba n Gani Agba.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…