Home Orisirisi Bilionu dola meji pere ni Dangote fi lowo ju Mike Adenuga  lo
Orisirisi - August 25, 2017

Bilionu dola meji pere ni Dangote fi lowo ju Mike Adenuga  lo

Ni bayii, Alhaji Aliko Dangote ati Dokita Mike Adenuga ni o lowo julo ni Naijiria.

Bakan naa, Dangote lo lowo julo ni gbogbo ile Afirika.

Sugbon atejade kan ti ajo Forbes, to maa n s’ofofo awon to lowo julo lagbaaye, fihan pe ti a ba fi dola wo o, alafo to wa laarin Dangote ati Adenuga ko fe ju.

Nigba ti gbogbo owo ati dukia Dangote je bilionu mejila ati aabo dola (12. 5 billion dollars), Adenuga ni bilionu mewaa ati aabo (10.5 billion dollars.)

Owo Dangote po ju bayii lo tele. Sugbon igba ti wahala de ba oro aje Naijiria lati 2015, ti owo naira di atemere fun dola, ni ipo re lo sile laarin awon olowo agbaye.

Sibesibe, baba ni baba n je ni oro Dangote.

Idi ni pe nnkan kan n bo lona ti owo re yoo tun fi takiti soke laipe yii.

Eyi ni ile ise fopofopo to sese n ko si Ipinle Eko, iyen refinery.

Bakan naa, kekere ni lamorin fi ju mi lo, ko see fi obe bu danu.

Bilionu dola meji ti Dangote fi sagba Adenuga naa kii se owo kekere. Ti a ba se e si naira, ile yoo kun rere ni.

Owo naa to eedegberin bilionu naira.

Awon olowo tabua miiran ti Forbes tun se atejadeohun ini won ni Iyaafin Folorunsho Alakija, (2. 1 billion dollars),  Ogagun Theophilus Danjuma  (1.7 billion dollars), Abdusalam Rabiu (1. 5 billion dollars), Alagba Tony Elumelu (1. 4 billion dollars), Dokita Orji Kalu ($1.5 billion), Alagba Tony Elumelu, (1. 1 billion dollars), Alagba Jim Ovia (1 billion dollars) ati Oba Otudeko (550 million dollars).

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…