Home Orisirisi Buhari ka iwe loju Adeboye nigba ti o s’abewo si  ni London
Orisirisi - August 18, 2017

Buhari ka iwe loju Adeboye nigba ti o s’abewo si  ni London

Aisi nibe ni ai ba won da si i. Gege bee ni ti Adari Agba fun ijo Redeemed Christian Church of God, Pastor E. A. Adeboye, ti oun naa se abewo si Aare Muhammadu Buhari ni ilu London lojo Jimoo.

Baba Adeboye naa lo se ‘E nle ni-beun, ara ko le bi’ si Buhari, ni ojo keta ti Senito Bukola Saraki ati Honorebu Dogara naa lo be Aare wo.

Bi a ko ba gbagbe, Minisita fun Oro Iroyin, Alhaji Lai Mohammed, naa ko awon oniroyin ijoba apapo leyin lo sodo Buhari ni laipe yii.

Ninu foto kan to sese jade, a ri ti Buhari n ka iwe kan nigba ti Adeboye n wo o.

A ko ti mo boya Bibeli ni tabi Kuraani. Bee, o si le je iwe iyanilori miiran to seese pe Adeboye lo fun Buhari.

Ni pataki, ohun idunnu ni eyi maa je fun opo eniyan, paapaa awon ololufe Buhari. Idi nip e bi o se n kawe fihan pe ara re ti ya daadaa, tori Yoruba bo, won ni alaisan ti a ba lori igi ope, to n ko ope, oro re kuro ni ‘Ara le tabi ko le’.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…