Home iroyin Májèlé pa ènìyàn 62 ní Kogi
iroyin - August 17, 2017

Májèlé pa ènìyàn 62 ní Kogi

Ko din ni eniyan mejilelogota to j’Olorun nipe ni ipinle Kogi lori ounje tabi omi mimu. Iwadii to gbopon si n lo lowo lori omi ati ounje ti awon oloogbe naa je gbeyin. Arun Iba Lassa ni opo eniyan koko ro pe o n fa iku ojiji naa, sugbon gege bi alaye ti Dokita Audu Saka to je Komisiona fun eto ilera ni ipinle Kogi se, o ni abajade esi ayewo ti awon se pelu awon eleto ilera Lagbaaye (W.H.O) se. Ko si ipa iba Lassa ninu ayewo naa rara.

Dokita Audu ni irora ti opo awon to ku maa n ke ni inu rirun ati igbe yiya. O ni gbogbo apeere yii ko ni nnkankan se pelu iba Lassa sugbon o han ninu ayewo naa pe majele wa ninu nnkan jije tabi mimu won ki won to ku.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…