Home iroyin Igí dá! Ọba Onígbòǹgbò wàjà
iroyin - August 15, 2017

Igí dá! Ọba Onígbòǹgbò wàjà

Kò sí jàgídí-jàgan níbi ìsìnkú  – Otunba

Ọba kan ni ile Yoruba je Olorun nipe ni aipe yii.

Alayeluwa naa ni Oba ti ilu Onigbongbo ni Ipinle Eko, Oba Munirudeen Yusuf.

Kabiyesi naa je eni to nifee idagbasoke Yoruba pupo, to si maa n ko eniyan mora.

Ipapoda naa waye leyin ose die ti Oba Yusuf se ayeye odun kewaa lori ite.

Lasiko ti won n sin oku baba naa ni ilana esin Islam, aheso iroyin so pe awon onisese kan binu.

Sugbon Otunba ti Onigbongbo, Oloye Lekan Dabiri, ni oro ko ri bee.

Iroyin aheso naa n ran kiri bii ina oye pe, ija ajaku-akata sele lojo isinku Oba naa, won ni opelope awon Soja ti Maryland mule ti pelu awon olopaa ni ko je ki awon kan wu oku Oba ki ile to mo.

Otunba ni ko si ohun to jo iru aheso bee, koda okan ninu awon omo Oba naa ti o ni ki a fi oruko bo oun ni asiri ni bi Otunba se wi gele naa lo ri. O ni ko si ija rara, bi o tile je pe awon onisese wa lale ojo naa lati wa ki awon ku aseyinde oba, eyi ko je tuntun si awon nitori pe awon elesin kirisiteeni naa wa ki awon. Loooto ni Oba ye ko maa se esin meteeta sugbon esin Musulumi ni esin Oba yii lati ile. Oba si maa n lo Mosalati lati ki wakati marun-un re, ni eyi ti ko je ki ariyanjiyan sele lori bawo ni a se fe sin oku. Awon Aafaa lo kirun si baba lara, awon si sin won gege bi ilana esin musulumi.

Otunba ni pipapoda Oba naa si n mu awon lotutu titi di asiko ti a ba won soro yii, nitori pe awon ko ri orun iku loju baba naa. Otunba ni boya ara si ti n soro fun Oba naa lo je ko tenu mo iwe lati ko itan ati ise Onigbongbo ati Awori jo. Oruko iwe naa ni “Royal Reflections”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…