Home Orisirisi Àwọn asòfin Abuja ṣe ohun tó wù wọ́n lórí àtúntò Nàìjíríà
Orisirisi - August 3, 2017

Àwọn asòfin Abuja ṣe ohun tó wù wọ́n lórí àtúntò Nàìjíríà

Won tun dun mohuru mohuru mo Fashola

Awon asofin agba ni ilu Abuja ko sii tii sinmi jijaye oloba o. Lose to lo nikan, won se nnkan meji kan to toka si pe Olorun nikan lo mo ohun to le sele lojo iwaju.

Lona kinni, won se awon atunto kan si Iwe Ofin Naijiria ni bii ogbon ona. Kii se ese fun won lati se eyi, tori pe ise ti Naijiria ati ijoba ara wa (democracy) gbe le won lowo ni lati sofin.  Ibeere to le waye ni pe: Iru ofin wo ni won n se, ati iru awon ofin wo ni won n se atunse le lori?

Opo awon to nifee Naijiria gba pe bi enikeni ba so pe oun fe s’ofin, tabi se atunto ofin, ti ko ba menu ba awon ibi kan ninu iwe ofin wa, awada kerikeri lasan lo n se.

Iru awon abala ofin bee ni eyi to da lori atunto Naijiria funra re. Eyi ni awon amoye n pe ni restructuring. Bi Naijiria se wa bayii, to je pe Ijoba Apapo ni Abuja lo wa gbogbo dukia Naijiria maya, to n pin owo epo bo se wu u, to n pin owo ti awon asobode Customs n pa bo se wu u, to si n dari olopaa bo se wu u, ni ko je ki ilosiwaju ba orile-ede wa.

Nigba ti Naijiria si dara laye awon Awolowo, Sardauna ati Azikiwe, agbara wa lowo awon ijoba agbegbe, iye regional government bii Western Naigeria, Eastern Nigeria ati Northern Nigeria. Nigba naa, lara owo ti won ba pa ni won ti n taari die lo si ijoba apapo to wa ni Eko nigba naa. Eyi lo fa a ti won fi ri owo se idagbasoke awon ijoba agbegbe bee.

Eyi lo fa a ti Awolowo fi raaye rori daadaa, oun ati awon ti won jo sise po lati gbe ogo ile Yoruba ga. Won rowo na lori eto eko, ilera, ise okowo ati bee bee lo.

Bayii ni ile Yoruba fi di akoko lati ni telifisan, gbongan ere idaraya, eko ofe, iwosan ofe ati Cocoa House.

Sugbon ni kete ti awon ologun gba ijoba, ti kinni naa fi si odo awon ara Oke Oya, won ba fomula to gbe Naijiria  ro je. Won ko gbogbo agbara lo si Abuja, ti kaluku wa n ja ija ajakuakata lati debe.

Ohun to tun je ki nnkan naa buru jai ni pe opolopo nnkan ti a fi n sagbara ninu oselu ni won ti kodi re si Okeoya North. Lara won ni awon ipinle ti won pin ni ipinkupin-in.

Isale ni awon ipinle nla nla si wa, bii ti Oyo to si tobi gbangba-gbangba pelu opo eniyan. Ni oke oya, won fo awon ipinle kan si bii meta tabi jubee lo. Bee ti won ba n pin owo ni Abuja, oriojori ti ipinle ni won fi n pin in.

Bakan naa ni won se lori ijoba ibile. Bi apeere, ijoba ibile to wa ni Kano nikan fee to ilopo meji eyi to wa ni Ipinle Eko. Iru eyi lo bi Tinubu ninu nigba to je gomina Eko, to fi da awon ijoba ibile tie sile.

Ohun to tun sun mo eyi ni pe aifun awon ijoba gbagbe laaye lati maa da ise owo tiwon se lori awon alumooni, ki won wa maa san owo ori fun Abuja, ti je ki won ya ole afajo. Nigba ti won ti mo pe owo n bo lati Abuja, won kan n sun oorun asunjarunpa losan-an gangna ni.

Eyi lo fa a ti awon ajajagbara Niger Delta fi n pariwo, ti won si n se jagidijagan pe awon fe ki alumooni epo awon wa ni ikapa awon – iyen resource control. Won n ba opo ile epo ati paipu je, ti Naijiria si n padanu aimoye owo.

Awon eya Naijiria bii Yoruba, Igbo ati Naija Deta ni ki won se atunro Naijiria. Awon ara Oke Oya ni iro. Bee, bi a ko ba se eyi, ko le si idagbasoke kan to moyan lori. Ibi yii gan-an ni awon to nifee Naijiria ti ro pe awon asofin agba yoo gbe igbese gidi le lori. Sugbon gbogbo atunto ti won ni awon se, won ko menu ba eyi.

Ohun to fara pe eyi ni atunto si ajo olopaa. Opo eniyan gba pe ki aabo to peye to wa kaakiri, a gbodo ni awon olopaa ipinle – state police.  Ile Yoruba ati awon eya miiran ti pariwo pariwo, sugbon Oke Oya ko kobi ara sii.

A se wa n gbo pe awon asofin Abuja se atunto ofin lona to le ni ogbon (30) lai menu ba eyi?

Sugbon sa o, die lara awon atunto ti won fe se wulo fun idagbasoke. Lara won ni pe ki ijoba ibile da wa gedegbe, ki awon gomina yee te won mere.

Bakan naa, won ni o ye ki eniyan ti ko ba je omo egbe oselu kankan lee maa dije fun ipo Aare orile-ede yii, eyi ti a n pe ni independent candidate.

Okan ti won fe se ti opo eniyan maa gbadura ki Aare Muhammadu ma bu owo lu ni pe ki aabo wa fun awon naa ki awon agbofinro ma le se itopinpin won lori bi won n kowo je tabi won ko kowo je, eyi ti a n pe ni immunity.  Ti iru ofin eyi ba ti waye, a je pe o tan fun Naijiria niyen.

Ni ose to lo naa, won pon on ni dandan fun Minisita fun Oro Akanse Ise ati Agbara, Ogbeni Babatunde Fashola, pe ki o wa se alaye ohun to so nigba ti awon se atunto eto isuna, nibi ti won ti ge owo to ye ki won fi se ona Lagos-Ibadan Expressway.

Nigba ti Fashola lo ba won, won po o nifun debi pe o nilati toro idarijin lowo awon asofin amunimadaa naa.

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…