Home LÁGBO ÀRÍYÁ Ìpadà-bọ irúfẹ́ eré Alárìnjó ti Hubert Ogunde.
LÁGBO ÀRÍYÁ - August 2, 2017

Ìpadà-bọ irúfẹ́ eré Alárìnjó ti Hubert Ogunde.

Oludari ‘Troopers Arts Production’, ọgbẹni Michael Okorie ti sọ pe awọn ti ṣọtan lati maa ṣere alarinjo. Eyi to tumọ si pe wọn yoo ma ṣere ori-itage lati ilu kan si omiran.

Ọgbẹni Okorie n sọ eyi fun ajọ oniroyin Naijiiria ni ọjọ aje ọsẹ yi. Osọ pe irufẹ ere alarinjo yi ma ri si gbigbe aṣa ilu kan si omiran. O sọ pe awọn alarinjo to n lọ lati ilu kan si omiran ti wọn si n ṣe ere ori-itage ma n ni ipa lori awọn eeyan nipa bi wọn ṣe ri ile aye ati igbe-aye.

O sọ pe ere alarinjo ti awọn fẹ ji pada yi ma mu idagbasoke ba aṣa lorilẹ ede Naijiiria yoo si jẹ ki awọn ọmọ orilẹ-ede yi mọ aṣa wọn si. O ni ere alarinjo yi yoo bẹrẹ pẹlu ere kan ti akọle rẹ n jẹ “Ẹkun Iya Agba”, eyi ti wọn yoo lọ ṣe ni ibi mẹta ọtọọtọ. O ni t ba sakiyesi, awọn ọdọ ode oni o mọ aṣa ati iṣe mọ.

Ọgbẹni Okorie sọ e gbogbo aafin ilẹ Yooba ni awọn yoo ti ṣere naa. O ni awọn ma bẹrẹ ni ọdọ Ọba GBọlahan Timson ni ọjọ keji oṣun kẹjọ. Lẹyin eyi ni wọn ma gbelọ si ọdọ Ọba Tobarab ni isalẹ Eko ni ọjọ kẹta oṣun kan naa ni ago mẹrin irọlẹ. O ni awọn eniyan yoo ni anfani lati wo o ni Freedom park ni ọjọ kẹrin oṣun kẹjọ ni ago meje irọlẹ. O ni awọn ma gbiyanju pe igbaṣa kiri yi ko ni parun mọ.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…