Home Orisirisi Ìsinmi Ọlọ́jọ́ gbọọrọ
Orisirisi - July 22, 2017

Ìsinmi Ọlọ́jọ́ gbọọrọ

Awon omo ileewe ti gba isinmi bayii. Kin ni ipalemo emi ati eyin lori awon omo naa. Loooto ni ilu le koko bi oju eja, ko si owo nita, awon to lowo repete , iberu ajo EFCC ko je ki won fon-on sita. Awon owo kan tile ti maa jera mo inu ile pelu iberu EFCC. Awon miran maa ti jera nitori pe eni to koo sibe ti je Olorun nipe, ko si salaye ibi to koo si fun ebi tabi ara. Owo ti ko see salaye feni kankan ni. Ko si ise nita, iwonba ti onikaluku ni lo wowo mo, pelu eyi naa, awon ajinigbe ko je ki ilu o fara ro. Awon oloogun owo ati agbara okunkun naa ko fi ilu lorun sile. Kin lo de gan-an?

Hun un! “Ile aye ko saa ni le koko ki awa eniyan lo ree maa gbe ninu omi, awon eja lo ni inu ibu”. Awon Boko Haram naa si n sose ni awon agbegbe kan ni ile Hausa. Wahala yii po de bi wi pe, ijoba ipinle Eko gan an ni ki onikaluku obi je ki awon omo won wa ni sakani won fun osu meji isnmi yii. Ijoba ni ko si idanilekoo inu Olide bi o ti maa n wa ni gbogbo odun seyin. Awon akekoo Model College, Igbonla si wa ni akata awon to ji won gbe. Awon obi nawo, won ti nara sibe alo awon omo yii ni won ri, won ko tii rabo. Se awon ti ko ni igbagbo ninu Olorun ni won maa mo ohun to n je asa atubotan tabi egun tabi eewo? Olaju ti fere gba gbogbo ohun to dara lowo wa tan.

Ju gbogbo re lo, awa obi naa ni ise to po lati se nitori pe awon omo ileewe girama naa wa lara awon ti awon onise ibi n se amulo. E je ki a maa mo ibi ti awon omo wa n rin si. Omo o ki n dagba lowo obi, bi o ti wu ki o ga to tabi sanra to, omo naa ni won si je labe obi. E je ki a we ki a le jare oye. E je ki a pa ohun ini wa mo ni ibi ti agbara ba mo nitori ti o ba lo sonu pere, awon ti ko gbon to eni naa ni won maa wa daa lebi.

Loooto tun ni pe, ona ofun, ona orun ni Yoruba maa n wi. A nilo lati gbiyanju wa nnkan ti awa ati awon omo yii maa je, pelu bee naa, a ni lati fi oro ti won naa si inu alaale wa loojo, lose,losu titi ti won tun fi maa wole saa eto eko ni inu osu kesan-an. Orisiirisii ijo buruku, orin buruku,egbe buruku ti gbogbo re si n pari si idaluru. Ki oro wa to di owe “omo to ni iya oun ko ni sun, oun naa ko ni foju borun” e je ki a we na, ki a le jare oye.  A-ro-jin-le…

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…