Home iroyin Ìlérí ìjọba lórí ònà Ìṣàwò ń bọ̀ wá di mímú ṣẹ.
iroyin - July 19, 2017

Ìlérí ìjọba lórí ònà Ìṣàwò ń bọ̀ wá di mímú ṣẹ.

Ó ti lé ní oṣù mélòó kan tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ṣèlérí fún àwọn ará-ìlú Ìṣàwò ni Ìkòròdú pé wọ́n ma ṣe ọ̀nà tó wọ ìlú. Ìlérí ọjọ́ pípẹ́ tó n fa àárẹ̀ ọkàn ló mú kí ọ̀pọ̀ tó ń gbé ní àgbègbè náà sọ pé ìjọba Èkó ti gbàgbé àwọn, àwọn míràn gbàgbọ́ pé nǹkan ìjọba kìí yá. Pẹ̀lú gbogbo awuyewuye yìí, àwọn kookan tí ṣọ́ọ̀bù wọ́n wà ni ọ̀nà náà ti ń palẹ̀mọ́.

Ní báyìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ṣetán láti ṣe ọ̀nà náà. Ìròyìn yí jẹyọ nínú ìpàdé abẹ́lé nípa ìṣúná-owó tó wáyé ní Ẹ̀pẹ́. Ẹni tó ṣojú Gómínà ìpínlẹ̀ Èkó ní ìpàdé nà, Ọ̀gbẹ́ni Rótìmí Ògúnlẹ́yẹ sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti fọwọ́ sí ṣíṣe ọ̀nà náà. Ó sọ pé ọ̀nà ìṣàwò náà ni wọ́n ma ṣe dé Kọ̀ọ́nú tí ó sì ma jásí Arépo lọ́nà òpópónà Èkó sí Ìbàdàn. Ọ̀nà kan náà yí ma jáde sí Ṣàgáamù. Ó rọ gbogbo àwọn tó ń gbé lágbègbè náà kí wọ́n farada àkókò ná nítorí ìgbà ń bọ̀ wà dára.

Olùdarí Hitech Nigeria Limited, Ọ̀gbẹ́ni Evan Becker sọ pé mẹ́rin ni afárá ẹlẹ́sẹ̀ tó ma wà lọ́nà náà àtipé léènì méjì ni ọná náà ma jẹ́. Ibùsọ̀ ma wá ní ibi tó lápẹrẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…