Home Orisirisi Lai Mohammed ń jà fita-fita lórí ìdàgbàsókè àṣà àti ìṣe Nàìjíríà
Orisirisi - July 16, 2017

Lai Mohammed ń jà fita-fita lórí ìdàgbàsókè àṣà àti ìṣe Nàìjíríà

Minisita fun oro Iroyin ati Asa, Alhaji Lai Mohammed, ko fi idagbasoke asa ati ise pelu ise awon alariya lorile-ede yii sere rara.
Minisita naa ni igbagbo pe bi idagbasoke ba maa ba oro aje Naijiria, nibi asa ati ise ni yoo ti wa.
Idi niyi ti o fi n se oniruuru apero pelu awon to n sise asa ati ise kaakiri Naijiria ati ni oke okun.
Ni ose to lo, o ba awon agbasaga naa se ipade ni ilu Eko.
Ipade naa ni won ti fori kori lori ohun ti ijoba , awon onse okowo ati awon osere naa ni lati se lati mu ki ibukun maa wa ninu abala idagbasoke naa.
Bakan naa, ni ojo Aje ati Isegun ose yii, Alhaji Mohammed n se ipade nla miiran pelu awon eni oro kan.
Ipade naa da lori bi won se maa ri owo sii lati maa sise asa ati ariya, eyi ti won n pe ni culture and entertainment industry.
Ile Eko ni ipade naa ti n waye.
Gege bi minisita naa ti so, owo tabua wa nibi ise asa ati ariya.
O ni awon orile-ede bii Amerika, United Kingdom ati South Africa n ri opolopo milionu dola nibi asa ati ariya.
Minisita naa wa so pe ti Niajiria naa ba se ise naa bo se ye ko se e, a le maa ri ju bee lo tori awa gan-an ni ijinle asa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…