Home iroyin Àwọn adigunjalè fojú Baba Latin àti Odunlade Adekola rí màbo lọ́jọ́ Sátidé
iroyin - July 16, 2017

Àwọn adigunjalè fojú Baba Latin àti Odunlade Adekola rí màbo lọ́jọ́ Sátidé

 

… Latin ni, “Wakati meji la lo ninu igbo”

Olorun lo yo awon ogbontarigi osere meji kan lojo Satide, nigba ti awon adigunjale da won lona ti won si da ibon bo moto won.

Awon naa ni Bolaji Amusan (Baba Latin) ati Odunlade Adekola.

Gege bi Baba Latin se se alaye, o ni Ijebu Ode ni awon ti n bo nibi ti won ti darapo mo ere ita gbangba kan.

Ninu alaye to se fun iwe iroyin alatagba Premium Times, o ni nigba ti awon de oju ona Ilisan Remo si Shagamu ni awon baa won ole naa loju ona. Baba Latin ni moto Adekola lo wa niwaju. Bi o se kana won ole naa ati awon moto miran ti won da duro ni Adekola fe sare tonu moto pada. Sugbon awon ole naa bere sii yinbon mo taya moto naa, gege bi Latin se so.

O ni kabakaba ni awon mejeeji ba jade ninu moto won, ti won sare wo inu igbo lo.

Latin ni, “Wakati meji gbako la lo ninu igbo yii. Awon ole naa si inu moto wa, ti won ko gbogbo ohun to wa nibe. Won ko owo, won ko foonu ati gbogbo ohun ti won ri.”

O fi kun un pe ni deede agogo meje aabo ale ni isele naa se.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…