Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE Pàtàkì orúkọ nínú ọfọ̀,ògèdè àti àásán
ÀṢÀ ÀTI ÌṢE - July 9, 2017

Pàtàkì orúkọ nínú ọfọ̀,ògèdè àti àásán

Okan ninu awon ohun ijinle enu Yoruba to lagbara ni ofo,ogede ati aasan,gege bi ese -ifa se je ede awo ti a kii ku giiri lo. O lasiko ati idi ti a fi n lo o.  Se awon agba ni oro ro wale, o ro ki,o ro ku,o ro ke. Oro ni laarija ohun gbogbo nile aye.Ofo, awon agba omoran kan gba pe agbara Oro to leto ni ofo.Ohun ti a fo jade lenu, lati mu ki n ti a fe se.Ofo le e je fun nnkan rere tabi idakeji. Ogo rere nu eyi ti o wa fun aabo ara eni ati eyi ti o wa fun itoju eni. Ofo buruku naa pin si meji. Ofo buruku die, ni a n pe ni Ogede.Eyi ti o buru jai,ti o jasi pe eni ti o n pe e papa a gbodo je ero, bi bee ko,iya ti a fe fi je ewure tun le pada sori eni, eyi ni Aasan.

Se Yooba bo, won ni oruko omo nijanu omo,oruko se pataki bi a ba n soro ofo,ogede ati aasan, nile yooba. lgbagbo awon yooba ni pe gbogbo nnkan ti Olodumare da lo ni oruko ti n je. Yato si oruko ti tawo togberi mo, oruko asiri tun wa ti a le fi pe nnkan ohun ki o le e je.Ogede je n ti o gbona ti won fi n binu si eniyan. Bi nnkan ba dara ti o n toro, ogede ni won fi i so di jakujaku. Won n fi ogede paayan,won a si maa fi da airoju si aye elomii.  Ohun buruku gbaa ni won maa n fi ogede se.Ni opo igba, bi eniyan ko ba je ero sikun, ko le pe ogede.lru ogede ti o le be e ti a ko le pe lai je ero ni a n pe ni aasan

Yooba le lo aasan lati mu ki eniyan siwa hu. Eni ti ko jale ri le bere si jale, oba tabi ijoye ilu kan le maa siwa hu.N ti aasan wa fun ki eniyan maa si iwa hu.Aasan ni etutu. Awon eroja ti o je mo ero ni Yooba maa n lo, die lara re ni, ewe odundun, ewe tete,ewe rinrin, ewe woorowo, igbin, oori ati epo. Yooba  ni nnkan lowo o, be e won ki i sadede lo awon nnkan wonyi. Se Yooba bo,won ni ti ko ba nidii, ese kii dede se. Bi o tile je wi pe esin ati imo igba lode ti n gba a ,sibe, ralerale inu igba osun,o to somo tuntun doge.

Bakan naa, awon osere fiimu bii Fadeyi Oloro, Abija ati Eda Onileola si n se amulo ofo ati ogede ninu ise won.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…