Home Orisirisi Òfin Ìkòròdú kò m’Ọba, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìjòyè
Orisirisi - July 5, 2017

Òfin Ìkòròdú kò m’Ọba, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìjòyè

Oro kanle kan baale, yoo kan jeje ni mo jokoo mi lo n sele lowo bayii ni ilu Ikorodu. O ti to bi ojo meloo kan bayii ti ariwo BADOO ti gba gbogbo ilu Ikorodu kan. Iroyin fi to wa leti pe ti BADOO ati awon omo re ba wo inu ile kan, won maa rii pe won pa gbogbo eni ti won ba ba nile. Bi o tile je pe awon eniyan kan ni owo to dil ni esu n be nise, won ni nitori ise ti ko si nilu ti je ki gbogbo awon omo ti ko nise maa lo oruko Badoo lati fi jale ati lati fi se ise ibi miran ni ilu Ikorodu.

Oro naa ka awon olopaa gan-an laya ni eyi to mu ki won se ipade bonkele pelu olori ajajagbara OPC, Otunba Gani Adams ati awon ajo fijilante lorisiirisii. Lati ojo keta ni ipade naa ti n so eso rere. Owo ti te awon to le logorun-un. Owo te awon kan ti awon olopaa ko moo sii ti awon ara ilu dana sun won. Bi awon ara ilu se n sun moto ni won n sun awon eniyan ti won ba ti funra si.

Ofin ti wa jade lati odo won olopaa pe idajo owo ko dara rara nitori awon alaise maa wa ninu won. Ofin ti wa jade kaakiri pe gbogbo eni ti irin re ba jo mo agbegbe Ikorodu, ko jowo ma se rin loru, koda, awon to n rin losan-an gbodo maa mu kaadi idanimo dani ni gbogbo igba. Won ni ofin yi ko yo enikeni sile.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…