Home LÁGBO ÀRÍYÁ Oogun ko ni Afeez Owo fi fe mi, Mide-Martins soro
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 2, 2017

Oogun ko ni Afeez Owo fi fe mi, Mide-Martins soro

 

Osere fiimu ti a mo si Mide Martins ti so fun awon to n gbe enu ni igbekugbee lori igbeyawo oun pelu onifiimu pataki miiran, Afeez Owo, pe ki won jowo yee so isokuso nipa awon.

O ni ife ti Afeez ni si oun po pupo, ti ko si see fie nu so.

O so pe oun naa ni ife re gidigidi tori o je eni to maa n wa fun oun ni gbogbo igba.

O ni o maa n se ojuse re gege bii baale ile, ti kii sii je ki iya o je oun ati awon omo oun rara.

Eyi lo je ki Mide-Martins so pe oun ti gbo pe awon kan n so pe oogun abenu gongo ni Afeez fi fe oun, se awon kan si gba pe oogun ife wa.

O ni aheso oro ti ko lese nile rara ni eyi. Mide wa tenu mo o pe ife otito lo joba laarin won.

O ni awon kan to so pe aarin awon ti daru ni nnkan bii odun kan seyin ko mo ohun ti won n so ni.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…