Home ÀRÒJINLẸ̀ Ẹ̀yà méjì péré ló wà ní Nàìjíríà
ÀRÒJINLẸ̀ - July 1, 2017

Ẹ̀yà méjì péré ló wà ní Nàìjíríà

Afiwe orin “Precaution” ti Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ni mo fe fi we alaye ti Emir Kano, Muhammadu Sanusi to se ni ilu Eko laipe yii, O salaye naa nibi ifilole iwe Olaniwun Ajayi.

Gbogbo ina ogun ati ina ote ti awon odo Naijiria n da ni orin Barrister yii da le lori. O n je ko ye wa pe, ogun o da bi iyan, ko da bii amala ati wi pe ija ogun ko jo ti ija eede laarin oko ati aya. O si se afiwe re gege bii iriri re loju ogun, O ni oun o ki n se soja bareke lasan, o ni oun ba won doju ogun. O si daruko awon ogagun bii Adeniran lati ilu Ogbomoso, Oladipo Diya lati Abeokuta, Dokita Adelaja lati ijebu ati bee bee lo.

Barrister ni ko dara ki nnkan kekere sele, ki a ti maa yara so pe awon eya Hausa ni tabi eya Igbo tabi Yoruba. O ni eyi ko dara rara, O se apeere awon ilu togun ti ko ri ti ilu naa o jo ara mo, bi apeere ninu awo orin re to koo pe “Mo ti ba won de ilu Liberia kogun o to de, bi ilu Amerika nilu won jo o o, igba togun wolu, ilu won dahoro, omo ilu Liberia, won fee ku tan oo, awon toku nibe, ebi o je won o jolo moo,bi sikeletin ni won ri, gbogbo oro aje won lo pare loju won, ko mowo, ko mese, gbogbo won lo lo sorun …..” O ko orin na debi ti won ti n kun odidi olori ilu bi eni kun eran ati bee bee lo. O se afiwe ti ilu Botswan, Russia, Somalia, Rewanda ati bee bee lo.

Barrister ko die ninu orin ikilo oloogbe Haruna Ishola to so pe-

“Aro to loju, to nimu, to n dite mo ara ilu pe kogun o de, aanu won se miiii, bogun ba de aro ni lati bote lo, bogun ba de aro ni lati bote loo”…

Barrister ni, ko si ohun to buru ninu ki a pe ara wa jokoo ki a so ohun ti a fe ni itubi, inubi. O ni gbogbo ologun ti a ni, omo Naijiria ni won, gbogbo oloselu, omo Naijiria ni won, o ni kin wa lo de ti a ko jokoo yi tabili po, ki a se amulo “National Conference”. Ti a ko ba gbagbe, opo omo Naijiria naa lo ti n pe fun abajade tabi amulo “National Confab” ti aye isejoba Goodlock Jonathan. Ninu awo orin naa lo tun ti koo pe “ Ti n ba n be laye, maa pe mo wi temi, ti n ba peyinda tan, ke pe mo wi temi ….”.Awo orin yi jade ni asiko isejoba oloogbe Sanni Abacha. Eyin alarojinle mi gbogbo, e o rii pe ala oloogbe naa nilo adura ati isora.

 

Oro omugo lo n yato, bakan naa ni tologbon n ri ni alaye gomina ile ifowo-pamo-si ti ijoba apapo tele, Muhammadu Sanusi. O ni ija omugo pata-pata ni ki eniyan maa ja ija eya tabi esin. O ni Olorun to da wa, mo idi to fi da wa po. O ni ko si tun si laakaye nibe ki nnkan-kan maa tii sele ki a maa so pe awon eya kan lo ba ilu yii je.

O ni boya ni a mo pe “ko tii si eya kankan to da ijoba se ri ni orileede yii”. O ni se bi gbogbo aye lo mo itan Obafemi Awolowo bo se dara to, nje ipinle Yoruba kankan tii pese iru Awolowo lati igba to ti ku?  O ni bee naa ni ipinle igbo kankan ko tii pese gomina bii Nnamidi Azikwe, ko tii si gomina bii Saudana bee si ni Niger/Delta ko tii pese asiwaju to se maa tele ni gbogbo ojo aye.

Sanusi ni opo omo Naijiria maa n bu enu ate lu Babangida pe oun lo ba oro-aje Naijiria je, ni eyi ti opo ko mo pe Olu Falae pelu Kalu idika Kalu o ki n se eya ile Hausa. O se apeere igba to wa ni CBN ti won n se atunto awon Banki wa gbogbo, ti “obe fi ba awon eniyan kan”. O ni nigba to kan idile Ibru, awon Urobo ni awon alale Urobo maa dide ogun si ijoba, o ni oun da won lohun nigba naa pe won ko le dide ija rara, abi ile ise meloo ni Ibru fi awon owo naa da sile ni agbegbe Urobo ni eyi to mu ki “apa awon to lopolo jabo”.

Awa ara ilu yii naa ni a ni Obasanjo ati Maurice Iwu se ojoro ibo ni odun 2007, se awon mejeeji wa lati agbegbe kan naa ni? Boya opo wa mo pe ko si ipinle kankan ti ko ni minisita ni Abuja, ti o tumo si wi pe, ti ilu ko ba dara, a je wi pe owo emi ati eyin ni o ti wa.

Sanusi ni opo wa lo maa n lo eya tabi esin fun imo ti ara wa nikan. Opo ni ko tun mo pe awon oyinbo amunisin to wa si Naijiria se awon eto kan sile ti awon eya Hausa ko fi ni kawe. “Won ni ti awon eya Hausa ba kawe, a maa ni opo olopolo pipe Musulumi”. Mo ti ko nnkan jade nipa re ri. Awon ti ko ye lo maa n so pe awon oyinbo feran eya Hausa ju awon eya to ku lo, iro funfun balau lo wa nibe. Ti mo ba fi ti eya se, n ko ni fi odo aye mi ja fun Abiola. Se bi omo Emir Kano ni mi sugbon mo je oguna gbongbo ninu “Pro democracy”, n ko tun ni je olori “Kudirat initiative for Nigerian Development (KIND) “. Naijiria ni opo eniyan to dara ni eya Yoruba, ni Igbo , ni Hausa ati awon eya to ku, bee ni awon eniyan buruku naa wa kaakiri eya ni Naijiria.

Sanusi gba omo Naijiria nimoran pe ki a pawo po ja fun, eto eko to ye kooro, ilera to pe, eto aabo to peye pelu gbogbo ohun amayederun ti awon orileede to ku n gbadun.

O te siwaju lati je ki o ye wa pe eya meji pere lo wa ni Naijiria, eya olowo ati eya talaka. Awon to lowo wa ni eya akoko, won n jeun po, mumi po, sise po, nigba ti awon ti ko ri jaje wa ni eya keji, won n se gbogbo nnkan po, won si n fi ikanra mo awon ti ko se ti ko ro ni ilu. Won si tun je ki awon olowo ilu maa lo won bi omi ojo. Won je ki awon olowo maa fi emi won wewu.

Sanusi se afiwe Naijiria pelu Orileede China ti iye won le ni bilionu kan aabo (1.6 billion) nigba ti Naijiria ko ti ju milionu aadosan-an lo (170 million). O ni China ni esin orisii marun-un, Buddhism, Confucianism, Taoism, Islam ati Christianty nigba ti Naijiria ni meji pere, Islam ati christianty. O tun se afiwe America to ni gbogbo esin ati gbogbo eya lagbaye, o ni won ko titori re ni awon fe pin. Sanusi ni kin wa lo ni wa lara ninu ibagbepo wa.

Sanusi tun gba awon odo nimoran lati wa nnkan se, o ni ki won ma se duro de ijoba rara nitori pe owo to ba dile ni esu n be nise. O tun ni “iku wa ajoku, aawe wa ajogba” lo le gba wa lowo awon oloselu. O ni ilaji owo ti oloogbe Abacha ji ko si wa ni orileede Switzerland bee si ni awon to n jii tiwon ni asiko yii naa kan n koo kiri iboji oku, salanga, ile ti won ko gbe ati bee bee lo. O ni ko si eyi to fi n da ise sile ninu won. “Aabo oro laa so fomoluabi ….”

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…