Home iroyin Awuyewuye lórí bàlúù tí Buhari gbé lọ sí Londoonu
iroyin - June 29, 2017

Awuyewuye lórí bàlúù tí Buhari gbé lọ sí Londoonu

Egbinrin ote ni oro Naijiria yii; bi a se n pana ikan ni okan tun n ru.

Abi bawo ni a se fe se alaye awuyewuye to tun n waye lori baalu ijoba ti Aare Muhammadu Buhari gbe lo si ilu London ni orile-ede England, nibi ti o ti n gba itoju?

O ti n lo bii osu meji ti Buhari ti n se itoju ara re, ti opo eniyan si n gbadura pe ki Olorun tete yonda alaafia to peye fun un.

Sugbon leyin pe awon omo Naijiria kan n binu pe Aare ko so pato iru aisan to n se e, awiidake tun ti bere lori ipinnu ijoba apapo lati fi baalu naa sile si London.

Idi ni pe owo goboi ni Naijiria n san fun awon ijoba oyinbo lori ibi ti won paaki re sile si.

A gbo pe egberun merin poun ni won n san lojumo, eyi to n lo sib ii egberun lona igba naira.

Ni pato, won ni ijoba Naijiria yoo ti san to bii ogorin milionu naira lori pe won paaki baalu naa sile.

Eyi fa a ki awon awoye kan maa so pe iwa apa, ati iwa taa ni yoo mu mi ni ijoba apapo n hu.

Sugbon sa o, olubadamoran agba fun Aare Buhari lori oro iroyin, Alagba Sheu Garba, ti so pe won paaki baalu na sile nitori aabo Aare ni.

O ni bi won se maa n se fun gbogbo olori orile-ede kaakiri agbaye niyi.

Lojo Alaaruba to lo, Gomina Ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose, so oro ibinu si ijoba apapo.

O ni won ko soooto rara lori ailera Aare.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…