Home Orisirisi Ọ̀dájú ni ọmọ Nàìjíríà
Orisirisi - June 27, 2017

Ọ̀dájú ni ọmọ Nàìjíríà

Aare ile wa, Mohammadu Buhari ni ailera n se lati bii osu meloo kan seyin, ni eyi to mu ki o maa paara ilu Oyinbo fun iwosan. “Iroyin eleje” kan ti wa gba gbogbo ilu kan pe Aare Buhari “ko le soro mo, ko le  rin mo, o kan laju sile lasan ni”. Eti oba nile, eti oba loko eniyan lo kuku n je bee, boya iroyin yi ta si awon to sun mo Aare leti ni abi Aare Buhari kan roo lokan re pe oun ko gbodo ma ki awon omo Naijiria ku odun itunu aawe.

Ede Hausa ni Buhari fi ki omo Naijiria ni eyi to fa awuye-wuye. Awon kan ni se awon eya Hausa nikan lo wa ni Naijiria ni? Awon kan ni se gbogbo wa ni a gbo ede Hausa ni? Awon kan ni se ede Hausa je ede ise ni Naijiria ni? Awon kan ni ki baba ti soro ni tawon. Ariyanjiyan yi lo tun gba gbogbo ilu kan lati ojo odun titi di asiko yii.

Bee ni awon kan ni, “a ni ki ole o sare, o sare, a ni ki o ju ti owo re sile, o se bee, kin ni e tile tun fe ki ole se bayii? Won ni iroyin pe baba ko le soro mo ni o gbode kan tele, igba to si ti wa soro bayii, o ye ki abuse o buse ni, ko ye ki awon tun maa ba ara awon ja. Olorun nikan lo le ba wa se e ni Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…