Home iroyin Túndé Bákàrè f’ẹnu ré ikú kúrò lórí Buhari
iroyin - Orisirisi - June 22, 2017

Túndé Bákàrè f’ẹnu ré ikú kúrò lórí Buhari

 

. Awon kan ni o n j’owu Osinbajo ni

Oludasile ijo Latter Rain Assembly, iyen Pastor Tunde Bakare, ti so fun awon ti won n ro’ku ro Aare Muhammadu Buhari pe ki won tun ero won pa.

Opo awon ojise Olorun ni ko tii menu ba oro ailera Buhari, sugbon Bakare kii se ei to maa n fi oro s’abe ahon so.

Bi o tile je pe o salaye pe olori ti Naijiria nilo bayii gbodo je eni to ja fafa to si lakikanju, o so pe Buhari lo si wa ni ipo Aare bayii, to tumo si pe kii se Ojogbon Yemi Osinbajo.

Bakare ni oro iku kiku, owo Olorun lo wa, kii se ti eniyan.

O ni koda, laarin alaisan kan ati dokita to n wa alaisan naa, Olorun lo mo eni to koko maa ku.

Sugbon sa o, oro ti Bakare so pe Buhari ni eeku ida wa lowo re, ati pe kii se Osinbajo to n se fidi hee fun un, ti bi awon eniyan kan ninu.

Won ni etannu bi Bakare ko se ri igbakeji aare je lo si wa ninu re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…