Home Orisirisi Ẹnì kankan kò fún Moji Olaiya ní májèlé jẹ – Mọ̀lẹ́bí rẹ̀ sọ̀rọ̀
Orisirisi - June 12, 2017

Ẹnì kankan kò fún Moji Olaiya ní májèlé jẹ – Mọ̀lẹ́bí rẹ̀ sọ̀rọ̀

 

Awon molebi osere fiimu to di oloogbe laipe yii, Moji Olaiya, ti kede pe kii se pe majele lo pa a.

Won ni eni kankan ko fun un logun je, leyii to ja si pe iro ni oun ti awon kan n so tele pe ejo lowo ninu.

Molebi osere naa so eyi di mimo ninu atejade kan ti okan lara won, Ogbeni David Olaiya, bu owo si.

O ni abajade ayewo ijinle ti awon dokita se lori oku Moji fihan pe amuwa Olorun ni.

Won wa kan saara si gbogbo eniyan to ti n ba won kedun lati ojo yii, paapaa awon ajo onifiimu ti won seto isinku ati Asiwaju Bola Tinubu to gbowo sile.

Bakan naa, enikeni to ba fe ran awon omo oloogbe lowo le fi owo ranse si aka-n-ti yii:

Fund Ifo Adunoluwa Farombi
Bank: Diamond Bank
Account Number: 009121427.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…