Home LÁGBO ÀRÍYÁ Ipinle Eko si n rokeke lori ayeye aadota odun
LÁGBO ÀRÍYÁ - Orisirisi - April 26, 2017

Ipinle Eko si n rokeke lori ayeye aadota odun

Eto ayeye aadota odun ti won Ipinle Eko sile si n lo ni rebutu o, pelu orisiirisii eto to ni idanilekoo pelu ariya ninu.
Ere tiata pelu orin kan, eyi ti akole re n je WAKAA THE MUSICAL, ni won fib ere re lose to lo lohun, nibi ti won ti se afihan bi aye se n lo ni Eko.
Opo awon osere bii Bimbo Manuels lo dan mewaa wo ninu ere naa ti Iyaafin Bolanle Austen-Peters se agbekale re.
Bakan naa, ere onise nla pelu orin ati ijo miiran ni won tun ti n se afihan re ni Eko. Eyi ni won pe akole re ni FELA! THE MUSICAL, to so nipa igbesi aye akorin gnakogbi ti a mo si Oloogbe Fela Anikulapo-Kuti.
Lara awon eto miiran to tun n lo lowo ni wiwa oko oju omi ni awasere, eyi ti a mo si BOAT REGATTA, to n waye ni Eko, Badagry ati awon ibi miiran ti omi wa.
Orisiirisii fiimu naa ni awon eniyan yoo ni anfaani lati wo latari ayeye naa.
Lara re ni fiimu Tunde Kelani ti a mo si MAAMI.
Odun 1967 ni won da Ipinle Eko sile, ti Ogagun Mobolaji Johnson si je gomina akoko.
Lara awon to tun ti se akoso ibe ni Alhaji Lateef Jakande, Oloogbe Otedola, Ogagun Buba Marwa, Omooba Olagunsoye Oyinlola, Asiwaju Bola Tinubu, Ogbeni Babatunde Fashola, ti Ogbeni Akinwunmi Ambode si wa lori aleefa bayii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…