Home LÁGBO ÀRÍYÁ Egbe FIBAN ipinle Ogun fee seranti Gbenga Adeboye ati Toba Opaleye
LÁGBO ÀRÍYÁ - òpómúléró - April 26, 2017

Egbe FIBAN ipinle Ogun fee seranti Gbenga Adeboye ati Toba Opaleye

Egbe sorosoro, iyen Freelance Independent Broadcasters’ Association of Nigeria, FIBAN eka tipinle Ogun labe Alaga won, Akinyemi Olatoye, Alawiye Fediresan ti pari gbogbo eto lati seranti awon akoni sorosoro ori redio ati telifisan nni ti won ti di oloogbe bayii.

Awon akoni naa ni Gbenga Adeboye topo mo si Jengbetiele ati Oloye Toba Opaleye ti won ti figba aye won sise takun-takun fegbe sorosoro naa lorileede Naijiria.

Gege bi atejade ti akowe egbe naa, Ayinla Egba fi sita lojo Abameta Satide to koja lo ti so pe ogbon ojo, iyen ojo Sande to gbeyin ninu osu kerin ti a wa yi ni eto naa yoo waye ni gbongan H3 Events Centre, to wa ni adojuko ofiisi Immigration, Oke-Mosan, Abeokuta.

O so siwaju pe idanilekoo yoo waye lojo naa lati enu Alhaji Sheik Abdul Lateef Ademoye (Yah Satar) Oniwaasi Agbaaye. Bakanna ni won tun fee fawon omo egbe sorosoro to peregede julo nipinle naa lami eye, iyen Awoodu.

Aago mejila osan ni won yoo te pepe eto naa pelu adura. Opo awon agba sorosoro lorileede yi ni yoo wa nikale to fi mo Aare egbe naa, Desmond Nwachukwu.

Ohun ti a tun gbo nipe, kii se gbogbo eeyan ni yoo ni anfaani lati wonu gbongan H3 lojo naa nitori ti won so pe aso ebi ipa mefa ti won mu, eyi ti won ta ni egberun meta abo (#3,500) naira ni yoo je gege bi tikeeti to maa gbe eni kookan wole.
Bi a ti gbo pe weje-wemu yoo wa lojo naa, bee naa ni gbajumo agba olorin apala nni, Alhaji Musiliu Haruna Ishola yoo forin dawon eeyan laraya.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…