Home iroyin Awon alakowe ba Sefiu Alao se ayeye ojo ibi

Awon alakowe ba Sefiu Alao se ayeye ojo ibi

Afihan tun ti waye pe teru-tomo lo n gbadun ere fuji, paapaa ti Sefiu Alao, o.
Bi awon ti ko kawe se n gbo o ni awon to kawe n je dodo re.
Eyi waye lojo Jimoo, ojo nla to koja, nigba ti Sefiu Alao, eni ti a mo si Original Omo Oko, iyekan Ayanyemi Ayinla atoko-wa-gbowo-nile, tun fi okan kun odun re lori ile alaaye.
Sefiu ko lo fi okan kun odun re, Olorun lo fi kun un.
Opo eniyan ni ko tie mo.
Sugbon oga gba oniroyin kan, to tun je eni to ba Otunba Gbenga Daniel sise po nigba to je gomina Ipinle Ogun, Alagba Wale Adedayo, lo koko se atejade oro naa.
Oun lo lo ba Sefiu lalaejo, to wa se atejade bi awon se n sararindin nile re, latari ojobii naa.
Adedayo ko tii gbe oro naa sori afefe ti awon alakowe miiran se gba a lenu re, ti won so o dorin.
Nigba ti awon kan n sa Sefiu ni mesan-an mewaa, ti won n so pe Original Omo Oko ati Omo oko to gbo kira-kira, agba oje ninu ise iroyin miiran, Alagba Bamidele Johnson, so fun Adedayo pe ko ba oun gba awo orin ASO IBORA bo lowo Sefiu!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…