Home LÁGBO ÀRÍYÁ Àwọn olólùfẹ́ Barrister dojú ìjà kọ Wasiu Àyìndé k1 lórí ìtàn fújì tó pa
LÁGBO ÀRÍYÁ - Orisirisi - March 14, 2017

Àwọn olólùfẹ́ Barrister dojú ìjà kọ Wasiu Àyìndé k1 lórí ìtàn fújì tó pa

Ija nla tun ti n sele lagbo fuji bayii o.
Oro ija naa, kii se laarin awon osere meji.
Kii se pe Pasuma Wonder n ba Saheed Osupa ja. Bee kii se pe Obesere ati Wasiu Ayinde n digbo lu ara won.

Dipo bee, awon ololufe Alhaji Agba, Sikiru Ayinde Barrister, ni won n ba Wasiu Ayinde fa surutu nla.
Awon ni won n ja ija ajagbara fun Barrister, eni to di oloogbe ni nnkan bii odun mefa seyin.
Awon ololufe Barrister ni adie kii ku ki a da eyin re nu.
Won ni bi Dada ko le ja, o ni aburo to gboju.
Won ni bi Barrister ko tile si laye mo, awon ko ni gba ki eni kan te e mere.
Won ni ti a ba tile maa ri eni ti yoo ko iyan Alhaji Agba kere, ti yoo maa fenu saata ise nla to gbaye se, ko ye ko je Wasiu Ayinde KWAM 1, nitori ohun ti Barrister gbe se ni igbesi aye re, paapaa lori oro ise orin fuji.
Kin wa ni ese Wasiu gan-an? Ibeere yii se pataki ti a ba ranti pe Wasiu sese se ayeye ojo ibi re ologota ni.
Lasiko to si n soro ni Eko ni ojo bii meloo seyin, nibi apejo ARIYA REPETE ti oti Goldberg se, Wasiu kan saara si Barrister gege bii eni to se mewaa ninu ati dide re.
Sugbon lasiko ti Wasiu n soro naa ni awon ololufe Barrister gbo oro kan to ba won ninu je gidi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…