Home ÀKỌ̀TUN Ọtí Goldberg ṣe bẹbẹ fún eré jùjú àti fújì
ÀKỌ̀TUN - LÁGBO ÀRÍYÁ - Orisirisi - March 5, 2017

Ọtí Goldberg ṣe bẹbẹ fún eré jùjú àti fújì

Ile ise Nigerian Breweries to n se bebe lojo Alamisi to koja, nigba to pe awon otookulu eniyan si apero kan ni ilu Eko, lori ona ti orin juju ati fuji yoo fi maa goke agba.
Lara awon akorin pataki to wa nibe ni Wasiu Ayinde ati Sir Shina Peters.
Bakan naa, awon amuludun Yoruba bii Yemi Sodiimu, Ambrose Somide, Damola Olatunji ati Kunle Afod naa ko gbeyin nibe.
Lasiko eto naa to waye ni Airport Hotel, ni Ikeja, awon onimo nipa orin, gege bii Ogbeni Hakeem Adenekan ati Ogbeni Kayode Balogun, to je aburo Oloogbe Sikiru Ayinde Barriister, se asaro lori idagbasoke orin fuji.
Ojogbon Tunde Babawale, to je oga agba kan ni Yunifasiti ti Eko, lo koko ba won so oro pataki lori ipa ti juju ati fuji n ko ni orile ede wa.
Nigba to n soro nibi aseye naa, Oga Agba kan lati Nigerian Breweries, Ogbeni Kufre Ekanem, so pe ife ti ile ise naa ni si asa ati ise Yoruba lo je ki won se agbateru re.
Gbogbo awon to peju pese nibe lo yombo Goldberg ati Nigerian Breweries lapapo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…