Home iroyin Efun n beedi: Omolara gun oko afesona pa
iroyin - February 22, 2017

Efun n beedi: Omolara gun oko afesona pa

Arakunrin kan, Sodiq Dauda, je Olorun nipe lairoti lojo Isegun to lo lohun-un, nigba ti obinrin afesona re, Omolara Olugbemi Abosede, ti obe bo o ni iha.
Won gbe Dauda digbadigba lo si osibitu ijoba to wa ni Ijebu Ode, sugbon epa ko boro mo.
Alukoro awon olopaa ni Ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi, se alaye pe oro owo tii boju ore je lo dija sile laarin Dauda ati Omolara.
A gbo pe inu osu kejila odun yii ni awon mejeeji fe segbeyawo tele, ki oro ise okowo to wa laarin won to di ariyanjiyan.
A gbo pe Dauda da okowo ise epo gas kekere kan ti o ni ki Omolara maa mojuto, sugbon ti oro iye owo to wole wa di fitina.
Odo awon olopaa ni Omolara wa bayii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…