Home òpómúléró FOLORUNSHO ALAKIJA: Obìnrin tó lówó jùlọ ní Nàìjíríà Ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú ìtẹ̀síwájú àti oríire rẹ̀
òpómúléró - February 19, 2017

FOLORUNSHO ALAKIJA: Obìnrin tó lówó jùlọ ní Nàìjíríà Ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú ìtẹ̀síwájú àti oríire rẹ̀

Awon eni ti ko gbon, awon eni ti ko moran, ani awon eniyan ti oju won dudu, won maa n so pe omo kan dara ju okan lo.
Ni pato, won a ni omokunrin dara ju omoobinrin lo.
Ti iru won won ko ba tii ri omokunrin bi, koda bi won ba ti bi omobinrin mewaa, won yoo si tun maa wa omokunrin kiri ni.
O seni laanu pe nibi ti awon miiran ti n wa awajura bee ni won ti n koba ara won.
Nje eni kan le so pe omokunrin kan wulo ju amuyangan eniyan to n je Iyaafin Folorunsho Alakija lo bi?
Pelu ogo Olorun, atata omo Yoruba yii ni obinrin to lowo julo ni gbogbo Naijiria lonii.
Owo ati dukia re ni o je bilionu meji dola ati die ($2.1), leyii to le ni irinwo bilionu naira (4]N400 billion).
Ah, AJE kuukale!
Iyaafin Alakija naa ni obinrin to lowo julo sikeji ni gbogbo Aafirika.
Koda, awon ojogbon kan ni oun lo lowo julo ni Afirika ni tele, titi di nnkan bii osu meloo seyin.
Ohun to wa se pataki loro Iyaafin Alakija nip e ona bi o se ri owo re ko ruju rara.
Oro re ko da bii awon olowo ojiji, olowo igbo kan to je pe mogomogo ati jibiti ni won fi ko oro jo.
Idi niyii ti opo eniyan fi ni lati ko eko nla nipase igbesi aye Iyaafin Folorunso Alakija, omo bibi ilu Ikorodu, to fi ilu Eko se ibujokoo pelu oko re, Alagba Modupe Alakija, eni to je agbejoro pataki.
Lona kinni, awon obi Iyaafin Alakija fun un ni eko to ye kooro, ni orile ede yii ati ni oke okun.
Won ko so pe omobinrin ni, ki won kan ju u bii oko roba si ile oko.
Eyi lo fa a ti eko to ye kooro fi dapo mi irawo nla ti Olorun fun un tele, ti nnkan si bureke fun un.
Lona keji, won ko Iyaafin Modupe Alakija, oun naa si gba eko. O tun tun ara re ko.
Ohun to tun se pataki nipa itan igbesi aye Iyaafin Alakija ni pe eka eko to yan laayo je eyi to gbe ebun re yo.
Lasiko tiwon, ati titi di oni yii, awon obi kan maa n pon on ni dandan fun awon omo won lati ko awon eko kan bii dokita, loya tabi onisiro owo.
Sugbo ni ti Iyaafin Alakija, eni to ye ki a maa pe ni OLUOMO gan-an, eko ise akowe (Secretarial Studies) lo se.
Leyin eyi, o tun ko eko aranso igbalode (Fashion Designing) ni ilu oyinbo. Ko wa yani lenu pe eko mejeeji wulo fun un daadaa nigba to bere sii da ile ise sile.
Nje Iyaafin Alakija wa je egbe okunrin ogorun tabi egbe aimpoye dokita bayii?
O tun se pataki lati ranti pe Iyaafin Alakija je eni kan to tete mo odo to fe da orunla si.
Eyi ri bee nipa pe ko pe pupo nidii ise onise. Loooto, o sise akowe die ni Sijuade Enterprises ni ilu Eko, ko tun to wa sise ni First National Bank of Chicago.
Iyaafin Alakija ko je ki ise onise o wo oun loju ju. Bayii ni o se da duro funra re, to si da ile ise ibi ti won ti n ranso, iyen Supreme Stiches, sile ni ilu Eko.
Kerekere, Iyaafin Alakija da ile ise miiran, Rose of Sharon House of Fashion, sile.
Ka to wi ka to fo, nibi ti opo obinrin egbe re ti maa se isekuse kaakiri lati maa gba owo lowo okunrin, Iyaafin Alakija bo sinu owo epo robi, ti o si di eni to da ile ise epo to ti gboregejige sile, eyi ti a mo si Famfa Limited.
Lonii, bi ile san bi kosan, awo laa wo. Iyaafin Alakija lobinrin to lowo julo ni Niajiria lonii, ti o si le ra aimoye milionu okunrin pa.
Sugbon Alakija kii na owo re basubasu. Kii fi owo re re eniyan je. Awon ti won mo o dele so pe kii sii se gaaru si baale re loode.
Dipo bee, o ti na opo owo fun awon alaini, debi wi pe o da The Rose of Sharon Foundation, nibi ti won ti n seranwo awon opo ati alaini miiran, lowo.
Nipa bayii, pelu idunnu ati ayo ni IROYIN OWURO fi gbe ade OPOMULERO YORUBA le Iyaafin Folorunso Alakija lori.
Ki Olorun tubo lora emi re ninu alaafia, ki owo re o si maa goke kiri.
Awon ti ko sit ii ni naa, ki Olorun o siju aanu re si won – ati si awa naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…